17/01/2025
OLASUMBO ❤️
Ó ṣẹlẹ̀ ní àṣálẹ́ ọjọ́ Ẹtì kan nínú oṣù Ògún ọdún 2001.
Mo jáde ní bíi aago mẹ́wàá-ààbọ̀ láti lọ mu àgbo jẹ̀dí ní ilé ìtajà ọ̀gbẹ́ni Tony torí òtútù pọ̀ púpọ̀.
Mò ń gbé ní agbègbè Sángo (ní òpópónà Pólì) nílùú Ìbàdàn níbí ńgbà náà, ilé wa kò jìnnà rárá sí ilé ìjọsìn Olùṣọ́àgùntàn Femi Emmanuel tí orúkọ ìjọ rẹ̀ ń jẹ́ Living Spring Chapel.
Ṣọ́ọ̀bù Tony jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ṣọ́ọ̀bù tó fara sọ odi Bárékè àwọn ọlọ́pàá tó wà lágbègbè Sángo. Ibẹ̀ sì jẹ́ ibi ìgbafẹ́ tí gbogbo àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin àdúgbò fẹ́ràn láti wá máa ṣe fàájì lásìkò ìgbà náà.
Mo fònà gáú sí ṣọ́ọ̀bù Tony, mo sì mu gàásì àgbo jẹ̀dí kan.
Bí mo ṣe fẹ́ fònà padà láti máa relé, ṣàdédé ni arábìnrin kan pẹ̀lú àpamọ́ rẹ̀ rìn súnmọ́ mi, ó jọ bí ẹni wípé ó nílò ìrànlọ́wọ́. Mo rosẹ̀ láti gbọ́ ohun tó fẹ́ bámi sọ.
"Arákùnrin, ẹ jọ̀wọ́ mo nílò ìrànlọ́wọ́ yín ni o..." Arábìnrin náà ń gbọ̀n lóhùn, bẹ́ẹ̀ lèmi náà tẹ́tí bẹ̀lẹ̀jẹ́ láti fẹ́ gbọ́ ohun tí yóó wìí.
"Orúkọ mi ni Sumbo. Agara ló dámi. Ìlú Ògbómọ̀ṣọ́ ni moti ń bọ̀ láti wá ṣe àbẹ̀wò sí ọ̀rẹ́ mi tó jẹ́ ọmọ ilé ẹ̀kọ́ gíga Gbogboǹṣe tìlú Ìbàdàn, tó sì ń gbé ní Apẹtẹ. Ṣùgbọ́n bí mo ti gúnlẹ̀ ni mo wòye wípé kò sí ọkọ́ tín lọ sí agbègbè yẹn látàrí òjò àrọ̀ọ̀rọ̀dá yìí." Arábìnrin náà sọ̀rọ̀ pẹ̀lú ojú rẹ̀ tó lé fún omi ẹkún.
Ohun tí Sumbo sọ yìí nípa lílọ sí Apẹtẹ lásìkò òjò, pàápàá ní àṣálẹ́ jẹ́ ìnira ńlá tín kojú àwọn tín gbé ní agbègbè náà.
Nírú àkókò bẹ́ẹ̀, ó sàn kí èèyàn wá ibòmíràn sùn mọ́jú ju kí èèyàn ní òun ń lọ sí Apẹtẹ látàrí òpópónà tí kò dára nígbà náà. Àwọn ọkọ̀ akérò kìí tiẹ̀ fẹ́ láti lọ sàkààní ibẹ̀ rárá ju kí wọn ó fi owó kún owó ọkọ lọ lásìkò òjò àṣálẹ́. Ìwọ̀nba ọkọ̀ péréte ní ń rin ọ̀nà náà lásìkò tí à ń wí yìí, púpọ̀ èrò sì ni agara láti délé máa ń dá, pàápàá ní àṣálẹ́ bí òjò bá ti rọ̀.
Lálẹ́ ọjọ́ náà, ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn èrò ló kún ibùdókọ̀ Sángo tí wọn kò rọ́kọ̀ látàrí wípé kò sí ọkọ̀ tó fẹ́ láti lọ sí Apẹtẹ. Àsìkò náà sì rèé kò dàbí ìsinsìnyí tí oríṣiríṣi àwọn ohun ìrìnsẹ̀ mìíràn ti wà, bíi Ọ̀kadà àti Márúwá ẹlẹ́sẹ̀ mẹ́ta.
Sumbo jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tó lùgbàdì lálẹ́ ọjọ́ yìí torí kò le padà sí ìlú Ògbómọ̀ṣọ́, bẹ́ẹ̀ ni kò le dé ibi tó ń lọ látàrí òjò tó fẹ́rẹ̀ẹ́ le wú òkú ọ̀lẹ àti òpópónà tó ti bàjẹ́, pabanbarì ni wípé kò tiẹ̀ tún wá sí ilé ìtura alábọ́ọ́dé ni agbègbè Sángo, bí ó bá tiẹ̀ wà, ibo ni yóó ti rówó tí yóó fi gbà á? Kòì tíì sí ẹ̀rọ alágbèéká nígbà náà tó tilẹ̀ le fi pe ẹni tón wá lọ, tàbí pe ẹlòmíràn fún ìrànwọ́. Ó jọ wípé èmi nìkan ni mo le gbà á là lálẹ́ ọjọ́ à ń wí yìí.
Kámá parọ́ o, kò tọkàn mi wá láti gba àjòjì bíi Sumbo sílé lọ́jọ́ yìí, pẹ̀lúpẹ̀lù wípé mò ń dá gbé nínú yàrá kan nígbà náà ni, ṣùgbọ́n ẹwà Sunbo kò ṣe é ṣe kò gbà fún.
Sumbo kúnlẹ̀ ẹsẹ̀ méjèèjì wípé kí n dákun ran òun lọ́wọ́. Torí ó dàbí ẹni wípé èmi nìkan ló lè ṣe ìrànwọ́ fún un.
Lẹ́yìn tí mo pe Àró àti Ọ̀dọ̀fin inú mi, tí mo fi oókan kún eéjì, mo gbà, mo sí wí fún Sunbo kí ó tẹ̀lé mi máa relé.
Bí wọ́n bá gun ẹṣin nínú Sunbo lọ́jọ́ à ń wí yìí, ó dájú wípé kò níí kọsẹ̀, inú rẹ̀ dùn púpọ̀.
A délé tí mò ń gbé, mo sí ní kí ó ṣe bó ṣe wùn ún, àtiwípé ilé ni ilé e rẹ̀.
Gbígbọ̀n ló ń gbọ́n pìpì nítorí wípé ò ti dúró pẹ́ jù nínú òjò. Àárẹ̀ pàápàá mú u.
Mo yára ṣe tíì gbígbóná fún un, bákan náà ni mo fún un lóòógùn ara ríro. Láìsí tàbí-ṣùgbọ́n ebi á máa pa á, n kò sì jẹ́ kó béèrè tí mo fi wọlé ìdáná lọ. Kò pẹ́ rárá tí mo fi padà pẹ̀lú abọ́ sẹ̀mó àti ọbẹ̀ ẹ̀gúsí. Ó sì gbádùn rẹ̀ dọ́ba.
Lẹ́yìn tó jẹun tán ni mo bá a ṣe omi tó lọ́ wọ́ọ́rọ́ láti wẹ̀.
Ó fẹ́ sùn sórí àga, ṣùgbọ́n mo ní kó wá sùn sórí ibùsùn kan náà tí mo sùn sí, ó lọ́ra, ṣùgbọ́n mo kàn-án nípá fún un.
N kò le gbà kí àlejò mi ó kákò sùn lórí àga nígbàtí èmí fẹ̀ bí ọba ìdun lóríi bẹ́ẹ̀dì. N kò níí ṣe èyí lábẹ́ bótilewù kó rí.
Mo mọ èrò ọkàn arábìnrin yìí àti ohun tí ń bà á lẹ́rù, ṣùgbọ́n mi kìí ṣe ọkùnrin tí ń torí ǹkan ṣe ǹkan fún àwọn tó nílò ìrànlọ́wọ́ mi. N kò ṣe èyí rí látijọ́ tí mo ti délé ayé. N kò sì níí fìkan gbàkan lọ́wọ́ ẹnikẹ́ni tó bá nílò ohun kan tàbí òmíràn lọ́wọ́ mi.
Lẹ̀yìn ìpàrọwà, Sumbo gbà láti sùn sórí ibùsùn pẹ̀lú mi, a sì sùn lo.
Lówùúrọ̀ ọjọ́ kejì, Sumbo kúnlẹ̀ síwájú mi láti dúpẹ́ fún gbígbà á láti sun ilé mi mọ́jú láì béèrè fún ohunkóhun dípò.
Mo fi ọ̀nà ilé ìdáná hàn án, ó sì se ìrẹsì gbígbóná fẹlifẹli tí a jẹ.
Ó wẹ̀, ó múra, ó kí mi wípé ó dìgbà, ó ṣì bá tirẹ̀ lọ.
---
Lọ́jọ́ yìí kan náà ní bíi agogo méjìlá ọ̀sán, mò ń rejú lọ́wọ́ ni, mo gbọ́ tí ẹnìkan ń kan lẹ̀kùn jẹ́jẹ́. Mo dìde láti ṣílẹ̀kùn. Sumbo ni mo dédé rí.
Ojú rẹ̀ pọ́n. Ó hàn gbangba wípé ó ti sunkún dáadáa. Ó ń wò suu bí ẹni ilé ayé sú.
Ó yàmí lẹ́nu láti ríi lẹ́ẹ̀kan síi, mo béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ ohun tó ṣẹlẹ̀.
"Unkú ID, ìyà jẹ mí" bẹ́ẹ̀ lón wẹkún mu pòròpòrò.
"Kíló ṣẹlẹ̀?" Mo tẹ̀ ẹ́ nínú.
"Mo wá látodindi Ògbómọ̀ṣọ́ láti wá kí ọ̀rẹ́kùnrin mi níbàdàn níbí..., " Sumbo bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀.
"Bí kò bá sí ẹ̀yin tí Ọlọ́run lò fún mi lálẹ́ àná ni, mo sùn síta tán, díẹ̀ ló kù. Mo gba ọ̀dọ̀ ọ̀rẹ́kùnrin mi lọ ní kété tí mo kúrò níbí lówùúrọ̀ yí, obìnrin mìíràn ni mo bá ní yàrá rẹ̀ bí mo ti wọlé. Mo fẹ̀hónú hàn, mo sì bií léèrè ìdí tó fi fẹ́ràn láti máa kó obìnrin, lílù ló bẹ̀rẹ̀ sí í lù mí lójú aṣẹ́wó tó gbé sílé. Kò fi mọ lórí lílù nìkan, ó lé mi ẹsẹ̀ mi ò balẹ̀. Ha! ọkùnrin yìí yàn mí jẹ." Sumbo gúnlẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni aṣọ tó wọ̀ tutù fún ooru àti omijé.
Ìtàn rẹ̀ yí ṣeni láàánú púpọ̀, mo fẹ́rẹ̀ẹ́ mómi lójú. Mo pẹ̀tù síi lọ́kàn, mo fàá mọ́ra, mo sì dì mọ́ ọ pẹ̀lú. Mo ṣàkíyèsí bí oókan àyà rẹ̀ ti ń mí gúle-gúle bó ti ṣe wà mọ́mi tímọ́tímọ́.
---
Díẹ̀ báyìí ló kù tí ǹbá gbé Sumbo níyàwó.
A fẹ́ra fún bíi ọdún mẹ́ta, mo sì ní ìrírí àti ìmọ̀lára ìfẹ́ ojúlówó tí kò lábàwọ́n bí ti í wù ó mọ lásìkò náà. Sumbo dàbí àdàbà oníwà tútù, ẹwà rẹ̀ pẹ̀lú jẹ́ èyí tí mi ò rí irú u rẹ̀ títí dòní olónìí.
Mo ní ìfọ̀kànbalẹ̀ pẹ̀lúu rẹ̀, ṣùgbọ́n ó ṣeni láàánú wípé a kò padà fẹ́ra sílé.
---
Ẹ kúu déédé ìwòyí 🙏
Ọdún á yabo fún wa 🎄🤶🎅🌲
Ó tún dọjọ́ mìíràn ojọ́ọre 👌
©️Oladele Idowu Joseph
Yorùbá: Ọládàpò Olúdáre Peace'bàbá
Àwòrán📷 látojú òpó ayélujára.