06/07/2022
Ni ile Yoruba, won maa n fun omo ni oruko ni ojo kejo ti a bi tabi won si aye. Yoruba gbagbọ pe awọn orukọ ni agbara tobẹẹ ti wọn ni ipa lori igbesi aye, iwuwasi, iduroṣinṣin ati aṣeyọri ọmọ nitori re niyoruba e n a pa ni owe pe "ile l'a a n wo k'a too s'omo lo'ruko" . Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọmọ Yorùbá ni wọ́n ń fún ní orúkọ tí ó ju ẹyọ kan lọ lọ́jọ́ tí wọ́n ń ṣe isomo l'orúkọ wọn, idi abajọ ni pe awọn ọmọ tuntun gba orukọ lati ọdọ baba, iya wọn; awon obi ti o bi awon iya ati baba won ati awọn ibatan miiran ti o sunmọ won.
Ni opolopo igba, isori meji ni orukọ Yoruba
Orukọ Amuwaye tabi Abiso.
Apẹẹrẹ oruko amuwaye/ amutorunwa ni:
Ige: Omo ti o mu ese jade nigbati a bi.
Oke:
Ajayi: Omo ti o ko oju si ile nigbati a bi.
Ojo/Aina: Omo ti o gbe ibi ko orun nigbati a bi. Aina ni Obirin, Okunrin si n je Ojo
Dada Omo ti irun ori re ta koko nigbati iya re bi.
Ilori: Omo ti iya re ko se nkan osu rara ki iya re to lo'yun re.
Taiyewo/ Taiwo: Toaiyewo omo ti o koko jade ninu iya won ninu awon ibeji
Kehinde: Ake'yindegbe'gbon/ Ake'hindegbe'gbon, yoruba gbagbo pe keyinde ni egbon taiyewo gege bi oruko yi ti fihan.
Oni: Omo ti o ke pupopupo, ti o ko lati dake ekun ni si sun nigbati a bi.
Abidemi: Omo ti iya re bi ni'gbati baba wa ni irinajo.
Idowu: Omo ti iya bi le'yin ibeji.
Apẹẹrẹ oruko abiso ni:
Ayowale, Ayanwole, Adeboga, Akinyale, Awonuga, Morenikeji, Ogunsola, Ojedele Fadipe, Eegundoyin, Omiyele ati bebe lo.