15/05/2026
Ọ̀mọ̀wé Cynthia Oniyelu Adekunle jẹ́ ògbóntarìgì àti akíkanjú obìnrin tó ń gbé àṣà àti èdè Yorùbá lárugẹ ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ àti ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà lápapọ̀.
Ó ti kópa púpọ̀ nínú ìtẹ̀síwájú èdè abínibí àti àṣà Yorùbá, ó sì ń ṣiṣẹ́ takuntakun láti jẹ́ kí èdè Yorùbá gbòòrò sí i. Òǹkọ̀wé alátinúdá ni, tó ní ìfẹ́ jinlẹ̀ sí ìdàgbàsókè èdè àti àṣà Yorùbá.
Òun ni Alákòóso Ẹ̀ka Àkóso ẹ̀kọ́ Yorùbá Àmọ̀dunjú, Directorate of Yoruba Language Proficiency ti Emmanuel Alayande University of Education, Oyo.
Tó bá di ọjọ́ Àyájọ́ Èdè Abínibí àti Àṣà Yorùbá 2.0, èyí tí ilé-iṣẹ́ Alakitan Akanbi Cultural Entertainment ṣe àgbékalẹ̀ rẹ̀, Ọ̀mọ̀wé Cynthia Títílayọ̀ Oniyelu Adekunle ni Olùgbàlejò Àgbà tí yóò gba gbogbo àwọn olùkópa ní àlejò.
📚 Àkòrí Ìdánilẹ́kọ̀ọ́:
ÌTÀKÙN AYÉLUJÁRA GẸ́GẸ́ BÍ IBI ÌSỌLỌ́JỌ̀O ÈDÈ, ÀṢÀ ÀTI ÌSỌDỌ̀TUN ÀWỌN EWÌ ALOHÙN YORÙBÁ.
🗓 Déètì:
Ọjọ́ Sátidé, ọjọ́ kẹfà, oṣù kẹfà, ọdún 2026
(Saturday, June 6th, 2026).
⏰ Àkókò:
Agogo mẹ́wàá òwúrọ̀ (10:00 AM).
📍 Ibùdó Ètò:
St. Mary Callista Hall,
St. Bernadine’s Grammar School, Oyo.
📞 Fún ìbéèrè tàbí àlàyé:
+2348077240728.
Ẹ má gbàgbé láti bá wa ṣe ẹ̀dà àtúnpín ìkéde yìí kárí ojú-ọ̀nà ayélujára yín.
Èdè àti àṣà Yorùbá jẹ́ ogún ìran wa; èdè náà kò ní kú, àṣà náà kò ní bàjẹ́. 🙏
Ẹ ṣeun púpọ̀, gbogbo yín la pè o, á máa retí yín lọ́jọ́ naa.
Alakitan Akanbi Entertainment LTD
Alakitan Akanbi AKEWI
́ÈdèÀtiÀṣà