25/06/2022
Asabi okin
ÀṢÀBÍ ELÉNÌYÀN
Asabi orente
Alasayan oge
Asabi eyinfunju owo
Eyinmenu kun
Ọlọhun adidun
Elete oyin
Oto ni adùn oyin
Oto ni adùn ireke
Oto ni adùn efo lemimeje
Otooto ni dídùn emu
Otooto ni dídùn oguro
Asabi to dun lete bí ọbẹ̀ osiki
Ó npa mi bí oti lile
Asabi mo nrohun mubo lojuran
Mo rohun wo lára re
Mo reyinju to npese
Mo ri ibadi to ńṣe a*o
Mo ri Alasabi mi ti omu rẹ nsewo simi
Mo wo awodami enu
Gigirise mi lé mọ́lẹ̀ kò lè lo
Nígbà tí mo rí ọmọge tí Eleduwa pari ìṣe sì lara
Asabi alasayan ewa
Asabi oloyaya temi
Aberin puyeke lereke
Afoju kini, fi gbogbo ara ṣe ayesi eni
A kii gbe okere mo dídùn obe
Mo de iyewu mo radun tí Asabi fi sagbeji ara
Ata to, iyo dun
Ó gbóná bí ajere
Orí rẹ pé bí alajo somolu
Alalubarika omo
Àdánlawo bí gilaasi
Ẹ ba mi wí fún Asabi ko bami relé.
Omo Ajanlekoko Ijinle