02/02/2023
Ẹyin àgbà ọ̀jẹ̀, ẹyin ọmọ eríwo, gbogbo ẹ̀yin ọ̀mọ̀ràn pátá ni mo pè sí Àkòdì yìí. Gbòógì nínú àwọn kókó ìjíròrò wa nínú Àkòdì yìí ni gbígbé àṣà àti èdè Yorùbá lárugẹ. Èdè Yorùbá pọnbele ni mo sì fẹ kí a máa lò. Ibi ìpàdé ojúlówó ọmọ Yorùbá ni gbàgede yìí jẹ. Ìdí rèé tí a fi pè é ní Àkòdì.
Ibùdó ìjíròrò ni, ó sì wà fún ìfikùnlukùn lórí ìṣẹ̀lẹ̀ àwùjọ Yorùbá àná àti ti òní. Bí ọmọ kò bá ìtàn, a sì bá àrọ́bá. Láríjà iṣẹ́ yìí níláti jẹ́ kí àwọn èwe wa mọ̀ wí pé kò sí bí ọ̀bọ ti ṣorí tí ìnàkí kò ṣe.
Kò sí ohun tó wà nínú gbẹ̀gìrì tí kò sí nínú ẹ̀wà! Kò sí adùn tó wà nínú èdè àjòjì tí kò sí nínú èdè Yorùbá. Ó kàn jẹ́ wí pé bí onígbá bá ṣe pe igbá rẹ̀ náà ni a ṣe ń bá a pè é. Ẹ jẹ́ ká yé pe igbá wa ni àkúfọ́, kí wọn ba lè jáwọ́ fífi kó ilẹ̀.
Gbogbo ohun tí yóò mú kí iná èdè àti ìwà ọmọlúwàbí ó gbèrú ni àwùjọ, pàápàá láàárin àwọn èwe wa, ni yóò jẹ wá lógún ní Àkòdì yí. Gbogbo ètò àti ìlànà tí èyí yóò ṣe jẹ́ ṣíṣe ní àṣeyanjú àti àṣeyọrí ni a óò sì gùn lé.
A fẹ́ ṣe èyí lati pe àwọn ògo wẹẹrẹ wa bọ̀ wá sílé nítorí wí pé ilé ni abọ̀sìnmi oko.
Èmi ọmọ yín, ọ̀rẹ́ yín, àti ìránṣẹ́ yín ní yóò dúró bí apèrò-sọ́kọ̀. Bí mo bá sì ti ń funrere àwọn àdúgbò tàbí ìlú tí ọkọ̀ wá ń lọ náà ni kí olúkúlùkù yín máa wọlé sọ́kọ̀.
Ọgá Ògo ni awakọ̀ wá, èyí ló jẹ́ kó dá mi lójú tó àdá wí pé èbúté ògo ni a óò gúnlẹ̀ sí bó bá wu ọlá Rẹ̀. Irú wá, ògìrì wá tí í mú ọbẹ̀ dùn, tí í mú ọbẹ ta ṣánṣán ni àwọn ọ̀nà ìṣọ́wọ́-gbéròkalẹ̀ wa yóò jẹ́. Èyíkéyìí nínú àwọn ẹ̀ka yii: ewì, ọ̀rọ̀ geere àti ìlànà ere-oníṣe ni a lè fi gbé èrò wá kalẹ̀.
A óò máa dá ara wa lẹ́kọ̀ọ́, a óò máa sọ ìrírí ayé, a ó fi ààyè gba ìbéèrè àti ìdáhùn. Ní ṣókí, ohun gbogbo tí Yorùbá dúró fún tàbí jẹ́ ní a óò máa wéwèé lórí rẹ̀ nínú Àkòdì yí.
Iṣẹ́ àṣeèdábọ̀ lè sọ ọmọ tó já fafa di ọmọ tó ń ká gúọ́; láti máà jẹ́ kí irú èyí ó wáyé ní Àkòdì, a fi ààyè gba ẹ̀fẹ̀ àti àwọn ìròyìn ìṣẹ̀lẹ̀ mériìírí tí ó kọ́ni lọ́gbọ́n.
Adédìí-ẹyìn-máṣìí àgbà ọ̀lẹ. Bí ìṣẹ́ kò pẹ́ni, a kì í pẹ iṣẹ́. Iṣẹ́ ti yá. Eré ti ya! Èyí tá a ṣe nírònà tó, ó yà nínú Àkòdì.
Ire o.