15/07/2022
ORO IFE SI OLOLUFE MI
Ife mi owon, enibi okan mi atata, eyin menugun temi ni kan soso, eyin fun jowo mi Ife, awe lewa mi anike, ibadi aran mi oreke, eyinju re to funfun lo nda mi lorun, ewa re tun mo lolo bi tomo tuntun, bebe idi re to tun so wowo yi nko, kini iwaju re mejeji ko tun nje gbadun, to ba tun rerin muse a dabi ki fi enu bo e lenu, otito ni egbin dara lawujo eranko, okin rewa lawujo eiye pelu, eku torofini sunwon ninu awon eku, ododo sunwon larin ewe, Ife mi iwo lo rewa ju larin gbogbo obinrin
Kini mole fi ife mi we na, enikan ni ki nfi we Ife labalaba si ododo moni Ife kini won ni si ara won, o ni ti labalaba ba bale ododo okan labalaba a bale pese, moni rara Ife ti moni si ololufe mi ju iyen lo, nitori kosi Ife ti labalaba leni si ododo lojo ti ododo bati re danu ni labalaba mawa ododo miran lo, o tun ni ife ti omi ni si eja ko kere, moni beni sugbon mi o le fi ife temi we omi ati eja, nitori ti won bani omi loma se eja jina won a ni iro ni, o wa ni ki fi Ife mi we Ife eleyele moni nitori kini o ni eiyele o ni ba onile je, ba onile mu ko di ojo iponju ko yeri, moro oro yi jinle dada sugbon sibe sibe moni Ife ti moni si ololufe mi ju eyi lo, o ni kini mowa fe fi Ife mi we gan, moni mole fi we Ife ti iyepe ni si ile, nitori ko si bo sele buru to iyepe o ni fi ile sile lailai, mo tun fi Ife ti moni we Ife ti irun ni si ori, bo tilewu ki won fi abe fa irun kuro lori, irun ori koni fi ori sile nigba kan, mo fi Ife ti moni si e we Ife ti erigi ni si eyin tofi di eyin mu pinpin, eni toba ma gba eyin kuro lowo erigi a wule ko inira ba gbogbo ara ni
Ife ti mo ni si e dabi Ife ti ekanna ni si owo eni ba ma gba ekanna lowo owo a wule se gbogbo ara ni Jamba ni, tun ma gbo Ife ti moni si e dabi Ife ti Ara ni si eje, ti eje ba nse are idamu tide ba gbogbo ara ni yen, Ife mi, ayo mi, eni bi okan mi, Ife ti moni si e dabi Ife ti Ara ni si eje, I love you so much, just tell your lover that I love you.........💖❤️💖❤️💖❤️💖❤️......
ỌRỌ ỌGBỌN GROUP
ÌMỌ ÒPIN SIBI KAN