21/08/2026
ÀTÙPÀ EYINJU OLODUMARE (Apa Kẹta)
IWE ITAN LATI OWO OMO OBA MIFUTAUDEEN ADEYANJU ADEBOYE
OJU IWE 32
Hunm,Lojo igbade oba Ajagungbade awon abiyamo ode orun ni won koko de si aafin oba naa,a*o kanna ni gbogbo won wo,bata to si wuyi ni won wo sii pelu,nse ni ojuu won gunrege daadaa,beeni eyin ojuu won naa mole kedere bii oju eja abori nisale odo,kosi enikeni to lee mo pe,awon ni agbalagba abiyamo aboja gbooro-gbooro,afinju eye tii je ni gbangba oko,agbalagba eye abiye bage bage ti won nti isalu orun fo wa si isalu aye,Iba eyin agbalagba 🙇,Afi alagbara eniyan to ba weju nikan loku to lee da won mo daadaa,Dide ti won de inu aafin kabiyesi ni won gbalo taara,won lo ree ki oba tuntun naa laafin,lesekese ti onitohun naa ti ri won bayi lo ti sare da won mo kiakia,o ki won teso-teso,o ki won tologun-tologun,awon iya yi tun sure fun oba naa,nibi ti won ti n sure fun oba yi lowo ni awon abiyamo ode aye naa ti ba won nibe,Awon wonyi ni ake kan-an ran,a la kan-an ran,afinju eye tii jeun niwaju oba,Awon abiyamo mejeeji parapo sure fun oba tuntun,Nse ni inu oba ajagungbade naa ndun yungba,leyin ti won sure fun oba yi tan,gbogbo won jade si gbagede won lo ree joko si ibi pataki ti won fi ijoko won si,E woo mio ni lee so orisirisi awon alejo tiwon wa sibi ayeye yi lojo naa lohun, nitori pe ero ti poju nibi ayeye naa,Se ti awon ladelade ni mo fe so ni abi ti awon loye-loye eyi ti enikeni kotile mo ibiti gbogbo won ti nroo wa witi-witi,nse lo dabi igbati awon eniyan ba n tuu jade lati inu ile kan lojo naa ni,gbogbo ona eyi to wo ilu Smsaworo patapata ni awon alejo ti ngba ibe wole,nse ni enu ibode kun fofo fun awon ero,bee ni iro ilu ayo naa ndun kikankikan,bi iro ilu ti ndun beeni sekere naa npariwo lotun losi,ese gbogbo awon ara ilu saworo lo pe wamu-wamu sibi ayeye yi lojo naa,iyaa wa Efunyela ati baale won ifaronbi aaye pataki ni won fi ijoko won si lori aga ola,ero ti po bii omi laafin,sugbon ao tii gburo ayanfe Olodumare naa,sugbon won ti fi aga abami eda naa ti yio joko si sile laarin awon loba-loba,nse ni gbogbo eniyan nwo aga naa bo se tobi to ati bo se rewa ju gbogbo awon aga towa ni ikale lo,awon ogberi eniyan nwo aga naa pe taani eni naa ti won fi aga nla to rewa naa kale fun?Gbogbo won duro won fe mo eni pataki naa gan-an to fe joko lori aga pataki yi,Laifi akoko sofo,eto ayeye igbade naa bere ni pereu,orisirisi awon eniyan ti enikeni ko da won mo ni won beresi ni wole kete-kete,won ti ko orisirisi Ade kale fun oba tuntun,Nigba toto akoko kan ayanfe Olodumare naa yo lookan lori ako esin nla kan bayi,bo se nbo bee lawon maarun tiwon je jagunjagun ode aye tiwon tun je jagunjagun ode orun nte lee bo leyin,Eni akoko ni OMOLARO,eni keji ni IKA-OMESI,iketa ni OLUPONNA AJAKAYE,,ikerin ni OLANU HAA HAA WOLE,eni karun si ni,IDAGBE tii gunmo lese laajin,awon wonyi ni.....🤷🤷
Onkotan ni omo oba Adeyanju..✍️✍️
Fun iranlowo eto yi. 07033678636
E sehun gan-an modupe lopolopo
Ipade wa tun di woo biojo ro,ire oo 🙇🙋♂️🙋♀️🙋