10/08/2026
✐:AKOLE ITAN
✐:OJU EWE 14
✐: ONIBANTE PELEJA
✐:IWE ITAN LATI OWO
KAFAANIY ONITAN AROGUN
yàrá naa ri jutujutu bẹni ibe nrun oba ajagungbade ti yagbe sara o Tito sara kosi eniti o fẹ tun ara rẹ ṣe olori ati aremo bo imu wọn olórí Abebi wipe ajagungbade kilode ti o ku kiakia kiosi gba ara rẹ silẹ ninu inira yii ati idojuti yii ? Ọba ajagungbade gbiyanju lati yii ori re kio sọrọ kio bewon kiwon jeki ohun tiẹ leba ọmọ ọdọ sọrọ kiwon fo ara ohun nu ṣugbọn kose se aremo wipe baami emi adeyemo mofi yin yanran moti tẹsiwaju ninu iṣẹ rere ti ense fún àwọn eyan inkan Timo nduro dè Niki e kú nkinle gùn ori apẹrẹ olórí Abebi wipe e sun dada ooo o so eleyi tan awọn mejeeji jade omije Jabo loju oba ajagungbade o kabamọ lati gbọ ọrọ sí àwọn alale lenu ni ọjọ keji ni arọ kutukutu wọn wo Ifawale olori Amope ati aremo adeleke jade ninu túbú wọn bẹrẹ sini fawọn losi ojubo ogun iwonba eyan diẹ ni o tele wọn nitori awọn kan nsinsun lowo eniti ọ mu ojuto ojúbo ati Abenilori tiwa ni ikale Abenilori ṣe ètùtù kékeré siwaju ki esho t**i ori ifawale bo igi ifawale bere sini sunkun Abenilori ge ori ifawale ori re bere sini yii ni ilele bi agbọn tiko tigbo dada adeleke ti esho danu ti o sigba ina oju esho naa Abenilori sọ ake sí adeleke aje naa sa ni ipako ki o to subu bi igi idana tio sì dojú bo'lẹ olori Amope pariwo o bere sini jà o fe ja ewon owo re sugbon awon esho dimu gidi gan wonti losi ibi igi tiwọn tibe ori ifawale wonte ori re onsi pariwo beni ọnsunkun gidi gan bi onṣẹ wo Abenilori tio l'omu ake ni ipako ọmọ rẹ tiotun wa ge ori adeleke silẹ olori Amope ku lekanna gige ori olori Amope wa rọrun fún Abenilori wọn wa gbe ori awon meteta ko awon eyan ilu onibante peleja tiwọn woran bere sini banuje lojiji wọn pada sí ilé pẹlu ibanujẹ ni aro ojo naa alago lù ago kakiri ilu o kéde wípé kí gbogbo wọn o korajo ni afin ni irọlẹ nigbati yíò fi di irọlẹ gbogbo àfín tikun ṣugbọn awọn eleye o yoju aremo jade o wipe ẹyin eyan ilu onibante peleja ooo Mósè ileri fun baba mi wipe matesiwaju ninu iṣẹ rere won bẹni masi sebe lati dabo boyin ni ọkan lara iṣẹ baba mi bẹni masi ṣe bẹ awọn eléye tiwọn wani abẹ baba mi tima fi tipatipa mu baba mi wọn bẹrẹ fún ẹbọ nkanka lati male sẹyin ni jàmbá bẹni baba mi ntinse nisinyi bami o lese mo won wa bami aremo sebi eniti o f'ema sunkun o dakẹ o tun tẹsiwaju o wipe awon eleye bere fún obìnrin tiko Timo ọkunrin metadinlogun wipe ti mioba fún àwọn ni obinrin tikoti mo okunrin metadinlogun iyun awọn ọmọ yin tiwọn bere Mósè fun won kiwọn lemo wipe mosetan lati tẹle aṣẹ wọn baba mi sebe ṣugbọn emi miole ṣe moni ifẹ yin Masi dàbo boyin pẹlu emi mi ọsan nkin ja pẹlu awọn ajé Juki nfi awọn ọmọ yin se etutu funwon lo aṣa ti baba mi ntinse lati àìmọye ọdún wonse ileri lati payin wọn ni awọn o fi inira kan yin , aisan ati are ọkan ṣe koye ki a yẹra fún wọn tabi ki amagbe Laisi wọn awọn eyan pariwo yeeeeeeeee ẹnikan wípé ṣugbọn aremo wa bawo lasẹ fe da eyan tio je eléye mo
Ọba ajagungbade losi idi igi ogede ninu aṣọ ogun o gbe etutu sowo o bere sini p'ofo Ifa rowa Ela rowa Ojupan mi kankan kin to ma ifa da mo salo salo kin to mo ogbedi alo ni mose kin to ko eru mi loba olofin ti toro ni toro lodi oluyoro niyoro eyin ona ona ati loseje te difa fun won ni ilu tese ogege nibi ti won da nibe oma won ni won fin ko won pa omo alara won pa omo ajero won pa omo orangun meji kiniyi kano orangun meji ni kokan mi won ni nitori kini oni toripe ije ti eje eran gbogbo enikan kole je oga be ije ti eje eran gbogbo eni kan kije eku asin be ije ti eje eran gbogbo eni kan kije ologini be ije ti eje eran gbogbo enikan kije idoro be ije ti eje eran gbogbo eni kan kije werejeje be ijeti ejeran gbogbo enikan kije atare be won ni baba ofo le ma npa yi oni kise ofo ooo oni oso ile yi sebi imule yin ni mose akibani mule akibani mule kada ise eni ru akibani mule kada alamori eni ru eiye dudu ori igin agba ooo sebi eiye ilu tiwa le nse nitori won ni eye abowo gegege eye abese gegege orunmila lo mu eye wolu nigbati won tikole orun bowa kole aiye, won de ibudo kan otororo won de ibudo kan otarara
nibiti enikan ko mona ibe
ti enikan ko mona irore
orunmila gbepo lo soja ejigbo mekun lota orunmila ni nibo le nlo?won ni awon lo si ode aiye, orunmila ni ki le fe lose? won ni awon fe lo so olowo di olosi,awon fe so eni totini di alaini,orunmila fohun Ope se e komope awon omo oun be ni be ni? won ni awon ti ba olodunmare pinhun pe awon ko ni pa omo orunmila, awon ko ni pa omo orisa nla, awon ko pa omo ogun, nigbana ni orunmila gba won laaye lati koja si ode aiye,bi won ti nlo ni olukaluku npiya won pade orunmila won ni awon fe pa omo orunmila,orunmila ni Eewo!!! ije ti won je eku ki ema se je oga, ije ti e je agbado, e ma se je ido, orunmila wa pase oniki ewe minisanminisan ko hu soju ona oso tonpe orimi nibi misan ko ma san won lo sorun,aje to ngbele pe ori mi sibi minisan ko ma san won lo sorun oo ota tofe dojú Kowa koma sanwon lo s'orun eyin iya mi ọoo ako aja aboju mejo ako aja boju merindinlogun eyin ni Mope e jemi ni ọoo Temi awọn iyami jade sí ajagungbade mẹta niwon oke ara won ti eniyan ni ṣugbọn lati ibi ìbàdí dé ilé ese ẹyẹ igunugun nio wani ibe ajagungbade wipe eyin iya mi Motun tide lati wa dupe fún yin tiẹ gba emi ati awọn eyan mi sile nigbati mo lero wipe ota ti bori mi miole dupẹ fún yin tan fún ore yin awọn agba sọrọ wọn wipe ajagungbade okare o han wipe o Ni emi imore a tigba etutu re gbe sile ajagungbade wipe ẹseun o gbe ebo naa silẹ o wipe mofe bere si ọkọ awọn agba wipe kitun ni ? Ajagungbade wipe mofe kio tun ma tẹsiwaju lati ma dabo bo awọn eyan mi t**i lailai Miofe ki ilu kankan ni agbara lati bori ilu mi k'ise ni asiko mi k'ise ni asiko awọn arọmọdọmọ mi mo ṣetan lati ṣe ohunkohun ti o bagba awọn agba min Kanle wọn wipe ajagungbade koda bi ibẹrẹ rẹ batie Tobi ṣugbọn ore iwonba kékeré ti a ṣe fún e o dupe ti a base jube lo wa tun sí ma dupẹ kini wama fún wa fún iṣẹ ti a fẹ Maba e ṣe yii?
✐••••••••••••••••••••••••••••••••••••••••••••••••••••••••••••••••••
To unlock next episode 50+Comment ✎ 20+follow ☞,100like ,30+ share ⌲
Ti ę ba fẹ ma ri itan yìí ká ki ẹ lọ sí orí profile Kafaaniy Onitan Arogun 👈 ki ẹ click sori LIKE
☞ ♡ ✎ ⌲
𝑳𝒊𝒌𝒆 𝑳𝒐𝒗𝒆 𝑪𝒐𝒎𝒎𝒆𝒏𝒕 𝑺𝒉𝒂𝒓𝒆