Akedegbede

Akedegbede ÀṢÀ ÀTI ÌṢE YORÙBÁ

26/08/2026

Bí Olúwa bá fún ẹ lówó,
Tọ́jú ẹ̀mí ẹ
Ohun ẹyẹ bá jẹ, lẹyẹ ma gbé fò.

Erin wó, Àjànàkú sún bí ÒkèKí olúwa dẹlẹ̀ fún Alhaji Taiwo Hassan Ogogo
23/08/2026

Erin wó, Àjànàkú sún bí Òkè
Kí olúwa dẹlẹ̀ fún Alhaji Taiwo Hassan Ogogo

21/08/2026

Oluwa jọ̀wọ́ mọ́ fi wá sílẹ̀ Fáráyé mú

16/08/2026

Àṣe sílẹ̀ ni àbọ̀wábá
Ohun a bá ṣe lónìí, la ó gbà lọ́lá.
Ẹ jẹ́ ká ṣe rere.

14/08/2026

Oluwa máse jẹ́ kaye pawátì bí aṣọ to gbó
Kí ìràwọ̀ wa ma se wọ̀ọ̀kùn
Ká má fi ojoojúmọ́ bágbà mu.

Kí ẹni tó ní ṣàánú ẹni tí kò níKá rán Ọmọ aláìlẹ́nìkan lọ́wọ́ débi gígaKí ẹni tí kò ní náà máse sọ̀lẹOhun tí a kò jìyà f...
13/08/2026

Kí ẹni tó ní ṣàánú ẹni tí kò ní
Ká rán Ọmọ aláìlẹ́nìkan lọ́wọ́ débi gíga

Kí ẹni tí kò ní náà máse sọ̀lẹ
Ohun tí a kò jìyà fún kii tọ́jọ́
Àtẹlẹwọ́ eni ni kìí tanni jẹ

Bí ẹni tí kò ní loni bá dépò àtàtà lọ́lá
Ranti àtẹ̀yìnwá, ka ran ẹlòmíràn lọ́wọ́
Má joyè bámúbámú ni mo yó
Kí ayé le rọ gbogbo wa lọ́rùn.

11/08/2026

Bí iná bá jó lóko, Mọ̀jàlà á délé ròyìn
Etí Ọba nílé, etí Ọba lóko
Ènìyàn ni wọ́n ń pè bẹ́ẹ̀.
Ẹ jẹ́ ká mọ irú ẹni àá fọ̀rọ̀ lọ̀.

09/08/2026

Bínú serí lobì yàn
ỌWỌ́ ẹni lafi tún ìwà ara ẹni ṣe.

07/08/2026

Inú ẹ̀dá kò dà bí òde
Inú jìn ó ju ọ̀run lọ
Bí a bá ń bá yàn rìn, ká mọ́ ṣọ́ra.

06/08/2026

Ìgbìyànjú kò dà bí Àṣeyọrí.
Olódùmarè májẹ ká Sàsetì Tọmọtọmọ

Address

Mesiogo
Ibadan
200005

Website

Alerts

Be the first to know and let us send you an email when Akedegbede posts news and promotions. Your email address will not be used for any other purpose, and you can unsubscribe at any time.

Shortcuts

Share